Ayo of Ibadan Profile picture
Ayọ̀mídé Adams. | Video Editor, Filmmaker & Documentary Photographer| Assignments 💌mrweezy15@gmail.com

Oct 3, 2020, 28 tweets

Ago mẹ́fà ló lù yìí, Àlàní ti bẹ̀rẹ̀ síí palẹ̀mọ́ fún wẹ̀jẹwẹ̀mu tí yíò sọ̀kalẹ̀ si ara òhun, àti àwọn tí ọ̀gá àgbà kan ní ilé iṣẹ́ wọn fi ìwé pè. Ní ilé ìtura Gódìn tọlìbù ni alárè ó ti j’àgbá, tí ǹkan ó gbe ǹkan hánu ni dédé ago méje tí àríyá ó bẹ̀rẹ̀ síí gbá

yùn. Kí ago mẹ́fà tó lù, orun ni Àlàní fi gbogbo ọjọ́ sùn nítorí ọjọ́ sátidè ni, iṣẹ́ á máa gb’omi mu púpọ̀ ni ààrin ọ̀sẹ̀, nítorí irú iṣẹ́ tí ó ń ṣe.
Ilé ìfowópamọ́ kan báyìí, tó wà ní ojú ọ̀nà Bódìjà ni Àlàní ti ń ṣe iṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oṣù kẹfà ọdún

2020, èyí tí a wà yìí, ni ó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, Àlàní ti ṣe dáradára fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọkùnrin. Ní inú oṣù kẹ́jọ tí a wà yìí, ni ó tún gba ìgbéga ni ẹnu iṣẹ́. Ilé rẹ̀ ti ó ń kọ́ ní Ajíbọ́dẹ náà, kò ní pẹ parí.

Òhun nìkan ni lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, síbẹ̀, ọmọ kan bíi igba ọmọ ni. Babárímisá ni Àlàní ọmọ Òpómúléró mọjaàlekàn, láti kékeré rẹ̀ ni Bàbá ti fi ilẹ̀ ṣe aṣọ bora. Ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ọrùn tí kò jẹ́ kí orí jábọ́, ìyá Àlàní ṣe gudugudu méje, yàyà mẹfà tó fi de ibi

gíga yìí. Bi Àlàní ti bọ́ síta ní ilé ìwẹ̀, pẹ̀lú tówẹ́lí tó lọ́ mọ̀ ìdí, tí omi sì n ro tó ní ara rẹ̀, ẹni tó bá rí ọkùnrin tí à ń sọ yìí ní àsìkò náà, àwòtúnwò ni yíò wòó lógun nítorí ẹwà tí Èdùmàrè fi jíìnkí rẹ̀.

Ojú rẹ̀ ló tàn rekete bíi iná alẹ́ yìí, irun orí

rẹ̀ kò kún jù, irùngbọ̀n rẹ̀ tó kún, tó sì bòó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ yìí, ni àwọn tó ń jí fún ṣe gba tirẹ̀. Àwọ̀ rẹ̀ Pupa, ó sì wùn ni jọjọ. Ìdúró rẹ̀ wu ènìyàn tó bẹ̀ gẹ̀ẹ́, tí àwọn kan tún ma ń bèrè lọ́wọ́ rẹ̀, bóyá ‘módẹ̀lì’ ni. Ká fi àsọdùn sílẹ̀,

Àlàní rí owó túnra ṣe. Bó ti para tán, ó kósí 'sẹ́ẹ̀tí' aláràǹbarà àti ṣòkòtò pénpé kan. O fi fílá kan dé ìmúra rẹ̀ lórí. Ṣé àwọn tó fi ìwé pè wọ́n sọ nínú ọ̀rọ̀ wọn pé “Dress code: Casual & keep it simple”. Nígbà tó fín lọ́fíndà sí aṣọ tán, ó bọ́ síta, ó sì

lọ fún àwọn ara ilé rẹ̀, ni 'fúlàtì' kejì ní kọ́kọ́rọ́. Òhun nìkan ló ń gbé ilé. Ẹ̀kọ̀kan ni àfẹ́sọ́nà rẹ̀ àti Ìyá rẹ̀ ma ń wálé.Àlàní kósí inú mẹ̀sí ọlọ́yẹ́, ó wo ago ‘Rólẹ̀sì’ ọwọ́ rẹ̀, ago mẹ́fà àbọ̀ ló lú, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ń fi àtẹ̀jísẹ́ ránṣẹ́

si lórí 'wọ́sọọ̀bù', wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ó ti kúrò nílé. Ṣùgbọ́n, kò dá ẹnìkan lóhùn. Ó ṣ'áná sí ọkọ̀, ó sì ń bá tirẹ̀ lọ sí òde. Rẹ́díò ọkọ̀ náà ń gbé orin' híbúhọbù' orísirísi sí afẹ́fẹ́ bí Àlàní ti ń g’ẹṣin lọ. Bi ‘Dafidó’ bá kọ tirẹ̀ tàán, ‘Bọ́nàBọì’

á gbàá ní ẹnu rẹ̀, ‘Wísíkidì’ náà àti àwọn olórin mìíràn ni gbẹ̀du wọn ń wọ akínyẹmí ara Àlàní.

Nígbà tó kúrò ní ilé rẹ̀ ní ìdí-àpẹ́, ọ̀nà ọ́físási mẹẹ̀sì ni ó darí ọkọ̀ rẹ̀ gbà, yíò gba ọ̀nà yẹn já sí 'kọ́sítọ̀mù'. Láti ibẹ̀, yíò nàá gba títì Awólọ́wọ̀,

tí yíò fi bọ́ sí Sángo. Jẹ́ríkó ni òpin ìrìn àjò kékeré yìí, nítorí ibẹ̀ ni ilé ìtura tó ń lọ wà.

Bí Àlàní ti dé iwájú Ìkọ́làbá, ní ìtòsì ‘Kọ́sítọ̀mù’ ni ọkọ̀ rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sií yọ ọwọ́kọ́wọ́, tí ó ń ṣe èsúkè léraléra. Kí Àlàní tó gbìyànjú láti yà níbi ìyànà

tó wà ní iwájú ilé ìwé Ìkọ́làbá lọ sí 'Kọ́sítọ̀mù', ọkọ̀ rẹ̀ gbé ẹ̀mí mì o. “irú kíni èyí ní àsìkò tí mò ń kánjú báyìí? Ah!” Ó ń dá sọ̀rọ̀ bí ó ti ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀. Àwọn èèyàn bíi mẹ́ta tí wọ́n ń ta èso oríṣiríṣi kan wà ní ibẹ̀ yẹn.

Àlàní ń gbìyànjú láti jí mọ́tò náà padà, ṣùgbọ́n, pàbó ni ó já sí. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tó ń ta ọjà yẹn, ó kọjú sí obìnrin tó kọ pélé kan báyìí.

Ó bèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ obìnrin náà, ó ní “ẹ jọ̀wọ́, ṣé mo lè rí ‘mẹkánìkì’ ní àárín yìí?” Obìnrin náà kọ́kọ́ wo apá

àláfíà rẹ̀ lọ sùn, ní ibi tí igi rẹ̀gẹ̀jì kán àti àwọn 'ṣọ́ọ̀bù' kan wà, ni ó ń wò. O pe ẹnìkan, “Bọ̀dá Sàráfà! Sàrá! Sàrá o! Bọ̀dá Sàráfà!” Ìyẹn náà dáhùn láti abẹ́ igi tó wà, ó ní “Kílódé tí ẹ̀ ń pariwo mi? Ṣé mo dákú ni?”

Obìnrin náà tún dáhùn, ó ní, “Àwọn ‘kọ́sítọ́mà’ ni wọ́n ń bèrè bọ̀dá Àlàbá o”

“Àlàbá ní ago méje? Ẹni tí ìyàwó rẹ̀ b'ímọ sílé. Bí ó bá ń rákòrò, yíò ti dé Mọ́níyà” Sàráfà fèsì padà.

Bí Àlàní ti gbọ́ báyìí, ó wo ojú obìnrin yẹn, onítọ̀hún náà wòó padá, Àlàní dúpẹ́

lọ́wọ́ obìnrin náà, o si padà sí ìdí ọkọ̀ rẹ̀ láti wá ọ̀nà míràn gbée gbà.

Bí iná ò bá tán l’áṣọ, ẹ̀jẹ̀ kìí tán l'éèkánná. Àlàní dúró ní iwájú ìlẹ̀kún àyè dẹ́rẹ́bà, ó fẹ̀yìn ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ rẹ̀, ó ń tẹ fóònù, mọkálìkì ni ó fẹ́ pé. Ó gbé fóònù sí etí ní ìrètí

pé, ẹni tí òhun ń pè, yíó gbe. Àwọn mọ́to ń kọjá ní méjì mẹ́ta lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí Àlàní lọ bá ní ẹ̀kan, ti ń palẹ̀mọ̀ọ́. Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, gbogbo ilé tí ó wà ní àyíká ni wọ́n ṣe 'géèti' sìí, tí ẹnìkan kò jáde tàbí wọlé ní àkókò yìí. Ago méje kọjá ìṣẹ́jú

mẹ́ẹ̀wá ló lù yìí, ṣùgbọ́n, ojú ọjọ́ kò tíì pajúdé, gbogbo ohun tó ń lọ ni èèyàn léè rìí.

“Ẹ̀ló! Ẹ̀ló! Ṣé ẹ̀ ń gbọ́ mi?” Àlàní ń bá mọkálìkì rẹ̀ sọ̀rọ̀.

Mọkálìkì fèsì, “Ẹ̀gbọ́n tó jaiyé jù! Mò ń gbọ́ yín”

Àlàní tún dáhùn, ó ní, “Mọ́tò mi ló takú ní ibi

ìyànà Ìkọ́làbá yẹn, mo dẹ̀ ni 'patí' tí mò ń lọ”

“Kílóṣe é gangan?”
“Ẹ wòó, mi ò mọ̀ ní kókó. Ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ máa bọ̀, màá san’wó yín”
“Mo wà ní inú àdúgbò kan ní Olódó, màá dé ọ̀dọ̀ yín l'áìpẹ̀ẹ́”

Bí Mọkálìkì ti wí báyìí tán, ọkàn Àlàní tún balẹ̀ díẹ̀,

nítorí, ó mọ̀ pèé, lọ́gán tí Ọkùnrin mọkálìkì yẹn bá dé, ọkọ̀ náà yíò gba ìwòsàn. Kó pẹ̀ ti ó pe mọkálìkì tàán, tí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tún ki orin b'ọnu nínú àpò ṣòkòtò.

Nígbà tí Àlàní mú ẹrù síta, ẹni tí ó ń pèé di Kúnlé, ìkan nínú àwọn ọ̀rẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n

dìjọ ń ṣisẹ́ ní Bódíjá. Bí ó ti gbé ìpè yẹn, irú ariwo tó ń jáde ní abẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kúnlé ní ọ̀hún fi hàn dájú pé àríyá ti ń sọ lálá.

“Ọ̀rẹ́ wa! Níbo lo wà báyìí? Àwọn 'bọ́ìsì' ti tẹ́ pẹpẹ fàájì sí ibí o! Kílódé? Níbo lo wà?” Kúnlé ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ bí

Àlàní ti gbé ìpè.
Àlàní náà tún dáhùn, ó ní, “Ọmọ! Oò ní 'bìlíìfù' ọṣẹ tó lọ yí mi ṣá? Mọ́tò mi ló takú o!”

“Ahh! Níbo? Ṣe ‘mẹkánìkì’ ti wà níbẹ̀ yẹn?” Kúnlé fèsì.

“O mọ ibi ìyànà Ìkọ́làbá lọ sí ‘Kọ́sítọ̀mù’ yẹn? Ibẹ̀ ni wèrè ara rẹ̀ paná sí! Mẹkánìkì ti ń

bọ̀ ṣàá” Àlàní ń sàlàyé fún Kúnlé báyìí.

Kúnlé tún dáhùn, ó ní, “Mi ǹ bá ní ko fi mọ́tò yẹn síbẹ̀ d’ọ̀la ṣùgbọ́n, ǹkan léè ṣeé níbẹ̀ mọ́júmọ́”

“Ahh! Ní àdúgbò tó ti dá yìí! Gbogbo àwọn ọlọ́jà tí mo bá, ni wọ́n ti lọ” Àlàní tún fún lésì.

Kúnlé ní, “Èmi àti Akin

ma 'díráìfù' wá bá ẹ níbẹ̀ kó má ṣe ìwọ àti mẹkániki nìkan”

“Wàá ṣere ọmọ ìyá mi! Ẹ bámi gbé àwọn jíjẹ mímu ti òdé wá o” Bi Àlàní ti parí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀, tó ní kí òhun fi ìkàlẹ̀ si nínú ọkọ̀, ni ó gbọ́ tí ọkọ̀ kan ń panà ní ẹ̀yìn ọkọ̀ rẹ̀.

Bi Àlàní ti gbé ojú wo ibẹ̀, mọ́tò àwọn agbófinró ni ó rí ti àwọn ọkùnrin méjì sì sọ̀kalẹ̀ láti inú rẹ̀. Ẹni wẹjú ni ẹ̀rù ń bà, Àlàní ò mira bí ó ti rí àwọn ọlọ́pàá nítorí kò ṣe ǹkan ẹ̀rù. Àwọn méjèèjì yẹn mú orí lé ọ̀dọ̀ Àlàní, ìkan nínú wọn kúrú, o

dúdú bíi ìsàlẹ̀ kòkò ẹ̀wà, ó sì ṣe ikùn gbẹ̀ndù bíi akèrègbè ẹmu, ó mú kóndó kan báyìí lọ́wọ́. Èkejì náà ga, ó dúdú, ó sì tún síngbọnlẹ̀, ìbọn ni ó fi ṣe ọ̀sọ́ sí ọwọ́ kan. Ọlọ́pàá tí kò ní Ìbọn, tí kò ní kùmọ̀, kòì tíì ṣe orò iṣẹ́ pé.

Bí ara wọn ti ń bù tì fún pàrágà tó, ìsọ̀rọ̀ sí wọn fi hàn gedegbe wípé, ọtí kò tíì gbé ọpọlọ wọn l'ugbò. Bí wọ́n ti dé ọ̀dọ̀ Àlàní, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé e ní ẹnu jó. Ní dédé àsìkò yìí, àwọn ọlọ́jà ti bá ti wọn lọ, àdúgbò náà ti dá bíi ìkómọ dìdìnrìn.

(To be continued).

À Rìn Fẹsẹ̀ Sí Ò Kan Máìlì - 📝 Ayọ̀ Adams.

Share this Scrolly Tale with your friends.

A Scrolly Tale is a new way to read Twitter threads with a more visually immersive experience.
Discover more beautiful Scrolly Tales like this.

Keep scrolling