Ayo of Ibadan Profile picture
Ayọ̀mídé Adams. | Digital Content Producer | Assignments 💌mrweezy15@gmail.com
Apr 8, 2022 5 tweets 3 min read
I have just dropped the collection titled Colors of an African market on @opensea

Kindly check it out and support
opensea.io/collection/col…

Floor price: 0.2 ETH ImageImageImageImage About:

Colors of an African Market shows the different activities of buyers and sellers at Bodija, a popular market in Ibadan, Nigeria. It is a reflection on the daily hustle and bustle of people from varying backgrounds who are united by a common location- the market.
Oct 4, 2020 8 tweets 3 min read
À Rìn Fẹsẹ̀ Sí Ò Kan Máìlì 2- 📝 Ayọ̀ Adams.
__
Kedere ni Àlàní ń rí orúkọ tí ó wà ní ara aṣọ àwọn ará ibí. Èyí dánkú yẹn ni wọ́n kọ “W.O Aliu” sí aṣọ rẹ̀, tí “F. Bánjọ” sì wà ní ti èkejì.Lọ́gán tí wọn ti dé ọ̀dọ̀ Àlàní, ni Aliu ti ṣí ìlẹ̀kùn iwájú apá àlàáfíà, tó sì ń tú ọkọ̀ ọlọ́kọ̀ bíi pé, ó tọ́jú ǹkan sí ibẹ́. Aliu wà ní ẹnu èyí, ni Bánjọ ń ju ìbéèrè sí Àlàní. Ó k'ẹhùn sọ̀rọ̀, ó ní, “Misita man! Kíni ìwọ ń ṣe níbí ní ìwòyí?”

Aliu gbé orí sókè láti ibi ìlẹ̀kùn tí ó k’orí bọ̀ tẹ́lẹ̀, ohun náà tún ní, “Àwọn
Oct 4, 2020 6 tweets 1 min read
Work is the Antidote for Poverty - JF. ỌDÚNJỌ

Work is the antidote for Poverty
Work diligently, my friend
Being industrious brings success
If we have no one to lean on
It is as if one is lazy
If we have no one to support us
We invest diligently in our work Your mother might be rich
And your father may have a stable full of horses
If you rely on them
You are on a journey to disgrace, I tell you.
Whatever one does not labour for
Does not last
That which you earned by virtue of hardwork
Lasts in the hand
Your arm is family
Oct 4, 2020 4 tweets 1 min read
Iṣẹ́ Lògùn Ìṣẹ́ - J.F. Ọdúnjọ

Isẹ́ lògùn ìṣẹ́
Múra sí Isẹ́ ọ̀rẹ́ mi
Iṣẹ́ ni a fí n d’ẹni gíga
Bí a kò bá rẹ́ni fẹ̀yìntì
Bí ọ̀lẹ làá rí
Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé
A tẹra mọ́ṣẹ́ ẹni
Ìyá rẹ le lówó lọ́wọ́
Bàbá rẹ sì le lẹ́ṣin léèkàn Bí o bá gbójú lé wọn
O tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ
Ohun tí a kò bá jìyà fún
Sé kìí leè tọ́jọ́
Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ́ fún
Ní ń pẹ́ lọ́wọ́ ẹni
Apá lará
Ìgúnpá ni ìyè kan
Bí ayé bá ń fẹ́ ọ lónìí
Tí o bá lówó lọ́wọ́
Wọ́n á ma fẹ́ ọ lọ́la
Tàbí kí o wà ní ipò
Oct 3, 2020 28 tweets 7 min read
Ago mẹ́fà ló lù yìí, Àlàní ti bẹ̀rẹ̀ síí palẹ̀mọ́ fún wẹ̀jẹwẹ̀mu tí yíò sọ̀kalẹ̀ si ara òhun, àti àwọn tí ọ̀gá àgbà kan ní ilé iṣẹ́ wọn fi ìwé pè. Ní ilé ìtura Gódìn tọlìbù ni alárè ó ti j’àgbá, tí ǹkan ó gbe ǹkan hánu ni dédé ago méje tí àríyá ó bẹ̀rẹ̀ síí gbá yùn. Kí ago mẹ́fà tó lù, orun ni Àlàní fi gbogbo ọjọ́ sùn nítorí ọjọ́ sátidè ni, iṣẹ́ á máa gb’omi mu púpọ̀ ni ààrin ọ̀sẹ̀, nítorí irú iṣẹ́ tí ó ń ṣe.
Ilé ìfowópamọ́ kan báyìí, tó wà ní ojú ọ̀nà Bódìjà ni Àlàní ti ń ṣe iṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oṣù kẹfà ọdún
Sep 25, 2020 10 tweets 3 min read
Díẹ̀kọ́lá fa Akin mọ́ra pẹ̀lú agbára, àwọn méjèjì ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ ètè ara wọn jẹ bi pọ̀mọ́ aláta súẹ́súẹ́. Nígbà tí Díẹ̀kọ́lá wọ inú 'ọ́fìsì' yẹn wá lẹ́ẹ̀kan, ó ti t'ilẹ̀kùn pa. Bí ẹnikẹni yóò bá wọlè, wọn á kan ilẹ̀kùn. Bí ètè jíjẹ ti ń wọra, Image bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sún láti ibi kan sii èkejì nínú 'ọ́fìsì' Akin. Síbẹ̀, iṣẹ́ ẹ́nú àti ahọ́n ń lọ ní rẹ́surẹ́su. Bí wọ́n ti sún sí orí àga kan báyìí, ni àwọn méjèjì bá bẹ̀rẹ̀ sí gba aṣọ kúrò ní ara wọn. Bí ẹni kíni ti ń sáré bọ́ ti èkejì, ni èkejì náà ń ṣe
May 9, 2020 14 tweets 3 min read
If D.O Fagunwa was alive and he writes about the Pandemic - (Ep. 1)
_____

Ni oru ojo kan bayii, owo ti pa, ese pa, o to asiko t'omokekere ile o gbodo sunkun omu. Lojiji, mo beresi gbo ti ilekun ile mi n dun, eru bami. Mo sokan giri, mo gba enu ona lo. "Ajilalaoso omo Akanbi, Image silekun ile re fun mi, odo re ni mo n bo" ohun na ke simi lati ibi ilekun. Eru tun bami, mo ro pe tani iru eda to le mo oruko emi ati iya mi loganjo?

Eyi tubọ bami l'eru gidigidi nítorípé bi wọn ti pe Kàkó ore mi pa nù. Bi motin wariri lọwọ bẹẹni mo ri ti iya mi yo