, 26 tweets, 11 min read
My Authors
Read all threads
Mo lọ sí Ìlú Olómìnira Bẹ̀nẹ̀ lóṣù kéje láti lọ ṣe iṣẹ́ kan. Nígbà tí iṣẹ́ parí, mo lọ káàkiri ìlú náà, mo dé ààfin ọba Dahomey, mo gbọ́ àrọ́bá, mo rí àwòrán lóríṣìiríṣìi, mo sì ka àkọsílẹ̀ ogun tí ó wáyé láàárín àwọn Ẹ̀gbá àti Dahomey.

#OgunDahomeyAtiEgba
Níwọ̀n ìgbà tí mo ṣì wà nínúu ọkọ̀ BRT ọlọ́yẹ́ ń'nú súnkẹrẹ fàkẹrẹ, n ó máa taari ìṣẹ̀lẹ̀ #OgunDahomeyAtiEgba sóríi gbàgede yìí. Ẹ máa bá mi ká lọ!
Lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹta ọdún-un 1851 tí alẹ́ ti ń ṣú bọ̀, tí òkùnkùn ti ń kùn díẹ̀ díẹ̀, àwọn ọmọ ogun agẹṣinjagun tí ó lọ ṣe alamí láti àárọ̀ ń padà bọ̀ sáàárín ìlú; àwọn olórí ogun àti àwọn ọmọ ogun-un wọ́n ti ń súre lọ sídìí ògiri #OgunDahomeyAtiEgba
Kírìríjingbin ìlú ogun ti ń dún káàkiri ìlú Abẹ́òkúta; gbogbo ọmọ ogun ń súré ṣẹ́ṣẹ́ lọ sí ògiri tí ó dúró gẹ́gẹ́ bíi odi ìlú; àwọn obìnrin àti ọmọdé ń sá kíjokíjo kiri òpópónà, wọ́n ń ké lóhùn réré, wọ́n sì ń ki àwọn ọkùnrin láyà. #OgunDahomeyAtiEgba #Yoruba
Kò sí ohun méjì bí kò ṣe pé àwọn ọ̀tá ti ń k'ógun bọ̀. Àwọn ọmọ-ogunbìnrin Dahomey ni wọ́n ń k'ógun bọ̀ nílùú Ẹ̀gbá lálẹ́ ọjọ́ burúkú Èṣù gbomimu tí à ń wí yìí.

#OgunDahomeyAtiEgba
Ọ̀yọ́ lágbára tí ó pọ̀ tí ó sì ti jẹ gàba lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú kéréjekéréje tí ó wà lágbègbèe rẹ̀ lórí, ara àwọn ìlú bẹ́ẹ̀ ni Dahomey. Ọdún-un 1738 ni Dahomey bọ́ sí abẹ́ ìsingbà Ọ̀yọ́.

#OgunDahomeyAtiEgba #Yoruba
Ẹ̀wẹ̀wẹ̀, àwọn òǹpìtàn kan sọ wípé láti ara ìran Yoòbá ni àwọn ọmọ Dahomey ti ṣẹ̀ wá, wọ́n sọ wípé láti agbègbè Odò Ọya ni àwọn Fon tí i ṣe ìbátan ìran Yoòbá ti ṣí wá sí Gúsù ibi tí a mọ̀ sí Dahomey lónìí, títí lọ dé Togo.
#OgunDahomeyAtiEgba #Yoruba
Ìtàn àtẹnudẹ́nu mìíràn sọ wípé nígbà ayée Houegbadja ni àwọn aráa Fọn bẹ̀rẹ̀ sí ní í pe ìlúu wọn ní Dahomey. Houegbadja náà ló sọ ibi tí ó kọ́ ààfin rẹ̀ sí; Abomey di olú-ìlúu Dahomey ní nǹkan bíi 1645 sí 1685.

#OgunDahomeyAtiEgba #Yoruba
Bákan náà ni àkọsílẹ̀ ṣàlàyé wípé ọmọ Houegbadja tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akaba lọ bẹ olóyè kan ní Gédévi tí oókọ rẹ̀ ń jẹ́ Dan wò, ó sì béèrè ilẹ̀ lọ́wọ́ọ rẹ̀ láti fi kọ́ ààfin, eléyun-ùn fún Akaba nílẹ̀ tí ó béèrè fún láti k'áàfin.

#OgunDahomeyAtiEgba
Àmọ́ Akaba kò ní ìtẹ́lọ́rùn, ó tún ń béèrè fún ilẹ̀ tí ó pọ̀. Dan kọ̀ sí i lẹ́nu, ni Akaba bá pa Dan, ó sì kọ́ ààfin-in rẹ̀ sórí orórìi Dan. Orí ikùn-un Dan; Danhomè ni Dahomè túmọ̀ sí. Orí ikùn (homè).

#OgunDahomeyAtiEgba
Akaba yìí kan náà ni ó jágbọ́n idà tí ó mú tó láti bẹ́ orí ọ̀tá péú lọ́wọ́ kan bí èlé ṣe ń bẹ ajá Ògún.

#OgunDahomeyAtiEgba
Nígbà tí Guezo jọba ní 1818 - 1858 ni ó gba Dahomey sílẹ̀ lọ́wọ́ Ọ̀yọ́-ilé. Láyée Guezo la ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú fún àwọn èèbó Portuguese àti France ní etíkun Ouidah. Ọmọ-ogun Dahomey tó bíi ẹgbẹ̀rún méjìlá àtẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọmọ-ogunbìnrin. #OgunDahomeyAtiEgba
Guezo fẹ́ gbẹ́sàn iye ọdún tí Ọ̀yọ́-ilé ti kó àwọn èèyàn rẹ̀ jẹ̀, ó fẹ́ yáróo rẹ̀ lára àwọn ìlú tí ó sùn mọ́ ọn bíi Abẹ́òkúta. Ni ó fi rán àwọn ọmọ-ogunbìnrin rẹ̀ láti lọ kó àwọn Ẹ̀gbá lógun lọ́jọ́ kejì oṣù kẹta ọdún-un 1851.

#OgunDahomeyAtiEgba
Àmọ́ kó tó dọjọ́ táwọn ọmọ-ogunbìnrin Guezo wọ̀nyí ó tó wọ ìlú Ẹ̀gbá, àwọn olóyè mélòó kan bíi Ṣágbuà àti Òkúbọ́nnà gbọ́ ìpè ogun olobó tí Ọ̀gbẹ́ni Forbes àti Beecroft ta wọ́n, wọ́n sì yára ṣiṣẹ́ àtúnṣe sí odi ìlú tó ti d'ẹgẹrẹmìtì. #OgunDahomeyAtiEgba
Bí Ṣágbuà, Òkúbọ́nnà àti àwọn ará ìlú ṣe ń ṣ'àtúnṣe sí odi ìlú méjì (ti Àríwá ìlà-oòrùn kò jẹ́ ṣíṣe, gbalaja ló wà), àwọn òṣìṣẹ́ ìjọ Ọlọ́run bíi Ọ̀gbẹ́ni Crowther kò leè jà, àdúrà ni wọ́n gbójúlé láti borí ogun. #OgunDahomeyAtiEgba
Ìṣàgá já s'Ábẹ́kùúta, tó bá jẹ́ wípé àwọn Dahomey lọ tààrà sí ìloro Abaka ní Àríwá Ìlà-oòrùn Abẹ́òkúta ni, wọn kò bá kó àwọn Ẹ̀gbá lógun lójijì, àmọ́ wọn kò mojú ilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Kàkà kí wọn ó kó àwọn ará Ìṣàgá lógun, wọn mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. #OgunDahomeyAtiEgba
Àwọn ará Ìṣàgá dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọgunbìnrin wọ̀nyí, wọ́n pa ẹran fún ètùtù, wọn sì jọ jẹ. Odi Àríwá Ìlà-oòrùn ni àwọn ọmọ ogun Dahomey fẹ́ bá wọlé, àmọ́ àwọn Ìṣàgá ṣì wọ́n lọ́kàn, wọ́n ní...

#OgunDahomeyAtiEgba #Yoruba #Egba #Abeokuta #Dahomey
"àwọn akọgun ló wà lápá odi ibẹ̀yẹn o, ẹ máà gbabẹ̀ wọlé, torí náà, ẹ gba Gúsù Ìlà-Oòrùn, àwọn yẹn kò lákínkanjú rárá, wọ́n ti m'ògiri gíga tí wọ́n sá sẹ́yìn-in rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ wípé ẹ ń k'ógun bọ̀, ẹ máà fòyà, ẹ gbọ́ sí wa lẹ́nu".
#OgunDahomeyAtiEgba
Àwọn ará Ìṣàgá tàn wọ́n jẹ, wọ́n tí wọ́n síwájú, wọ́n ní kí wọ́n ó máa jó lọ, àwọn ń wo ẹ̀yìn-in wọn, wípé àwọn ńbẹ lẹ́yìn-in wọn bíi iké. Àwọn ọmọgunbìnrin Dahomey tẹ̀síwájú, wọ́n béèrè ìgbà àti àkókò tí ó dára láti ṣígun, "ṣé lálẹ́?" #OgunDahomeyAtiEgba
Àwọn ará Ìṣàgá ní "ẹ kò fẹ́ẹ́ boríi wọn, àwọn ọkùnrin máa ń wà nílé lálẹ́, èyí yóò sì mú nǹkan nira fún-un yín, ẹ dúró di ìyálẹ̀ta, àwọn ọkùnrin yóò ti wà lóko, díẹ̀ tí ó wà nílé yóò ti sùn lábẹ́ igi ẹyìn."

#OgunDahomeyAtiEgba
Bí wọ́n ṣe ń jíròrò yìí, àwọn ará Ìṣàgá ti rán ẹnìkan tí ó kó eegun ètùtù tí wọ́n ṣe sí Abẹ́òkúta láti gbé e sí wọn létí wípé ogun ńbọ̀ lọ́sàn ọ̀la. Èyí ló fà á tí ó mú àwọn ará Abẹ́òkúta máa sá kíjokíjo kiri láti ṣe àtúnṣe sí odi ìlú gbogbo. #OgunDahomeyAtiEgba
Bí a bá kà á ní méní méjì, àwọn ikọ̀ ọmọgun Dahomey tó wà n'Íṣàgá yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ t'ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún; ọkùnrin 10, 000 àti 6,000 obìnrin, tójúu wọn pọ́n roro, t'éegun wọ́n le kankan. Ọmọ-ogun Abẹ́òkúta ò sì ju 8,000 ọmọgunkùnrin lọ.
#OgunDahomeyAtiEgba
Nígbà tí ó máa fi di ìdájí ọjọ́ Ajé, ìròyín ti kàn wípé àwọn ọ̀tá ti ń sún mọ́. Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, ìró ìbọn ti gba afẹ́fẹ́, èyí ti kéde wípé ogún ti bẹ̀rẹ̀.

#OgunDahomeyAtiEgba
Ilé Ọ̀gbẹ́ni Crowther sún mọ́ etí ògiri Gúsù Ìlà-Oòrùn, kò sì fi bẹ́ẹ̀ láàbò, ìyàwóo rẹ̀ ti sá lọ sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Townsend nítorí ibùgbée rẹ̀ tí ó wà ní Aké ní ààbò ju ibòmíràn lọ, tí Ọ̀gbẹ́ni Crowther sì dúró láti ṣe ìtọ́jú àwọn ajagun.
#OgunDahomeyAtiEgba
Òkúbọ́nnà àti àwọn ikọ̀ ọmọgun rẹ̀ jà fitafita létí odò Ìkíjà. Àwọn ènìyàn ń sá àsálà fún ẹ̀míi wọn, bí àwọn kan ṣe ń ké pe Ifá, làwọn mìíràn ń ké pe Ṣàngó, Ṣódẹkẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń ké pe Jésù kí ó wá gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ogun
#OgunDahomeyAtiEgba
Ìjàdù náà lọ fún bíi wákàtí mẹ́fà, ilẹ̀ ń ṣú bọ̀. Àwọn ọmọ-ogun Dahomey rí i wípé ọ̀rọ̀ kò wọ̀ mọ́, ni wọ́n bá ń padà sẹ́yìn, wọ́n rí i bí àwọn Ẹ̀gbá ṣe ń tú yáyá jáde látẹnu ìloro, ni wọ́n súre kàbàkàbà, ọmọgun Ẹ̀gbá sì lé wọn léré.
#OgunDahomeyAtiEgba
Missing some Tweet in this thread? You can try to force a refresh.

Enjoying this thread?

Keep Current with ỌMỌ YOÒBÁ

Profile picture

Stay in touch and get notified when new unrolls are available from this author!

Read all threads

This Thread may be Removed Anytime!

Twitter may remove this content at anytime, convert it as a PDF, save and print for later use!

Try unrolling a thread yourself!

how to unroll video

1) Follow Thread Reader App on Twitter so you can easily mention us!

2) Go to a Twitter thread (series of Tweets by the same owner) and mention us with a keyword "unroll" @threadreaderapp unroll

You can practice here first or read more on our help page!

Follow Us on Twitter!

Did Thread Reader help you today?

Support us! We are indie developers!


This site is made by just three indie developers on a laptop doing marketing, support and development! Read more about the story.

Become a Premium Member ($3.00/month or $30.00/year) and get exclusive features!

Become Premium

Too expensive? Make a small donation by buying us coffee ($5) or help with server cost ($10)

Donate via Paypal Become our Patreon

Thank you for your support!