ỌMỌ YOÒBÁ Profile picture
Olùfẹ́ àṣà. Ọmọ Yorùbá àtàtà. Ọmọ Oòduà t'ọkàntọkàn #Teacher 👉 @tribalingual #localization #translator 👉 @gvyoruba #Anthropologist #Farmer #Author
Nov 6, 2019 26 tweets 11 min read
Mo lọ sí Ìlú Olómìnira Bẹ̀nẹ̀ lóṣù kéje láti lọ ṣe iṣẹ́ kan. Nígbà tí iṣẹ́ parí, mo lọ káàkiri ìlú náà, mo dé ààfin ọba Dahomey, mo gbọ́ àrọ́bá, mo rí àwòrán lóríṣìiríṣìi, mo sì ka àkọsílẹ̀ ogun tí ó wáyé láàárín àwọn Ẹ̀gbá àti Dahomey.

#OgunDahomeyAtiEgba Níwọ̀n ìgbà tí mo ṣì wà nínúu ọkọ̀ BRT ọlọ́yẹ́ ń'nú súnkẹrẹ fàkẹrẹ, n ó máa taari ìṣẹ̀lẹ̀ #OgunDahomeyAtiEgba sóríi gbàgede yìí. Ẹ máa bá mi ká lọ!