My Authors
Read all threads
If D.O Fagunwa was alive and he writes about the Pandemic - (Ep. 1)
_____

Ni oru ojo kan bayii, owo ti pa, ese pa, o to asiko t'omokekere ile o gbodo sunkun omu. Lojiji, mo beresi gbo ti ilekun ile mi n dun, eru bami. Mo sokan giri, mo gba enu ona lo. "Ajilalaoso omo Akanbi, Image
silekun ile re fun mi, odo re ni mo n bo" ohun na ke simi lati ibi ilekun. Eru tun bami, mo ro pe tani iru eda to le mo oruko emi ati iya mi loganjo?

Eyi tubọ bami l'eru gidigidi nítorípé bi wọn ti pe Kàkó ore mi pa nù. Bi motin wariri lọwọ bẹẹni mo ri ti iya mi yo
simi o funmi ni iye odidẹrẹ pupa kan, o ni kin fi si inu epo pupa kin si fi le tiro si oju mi. Mo ṣe be, ketete ni mo si ri alujanu olori mẹwa kan ni yara mi.

Alujanu yii dudu hoho bi isale isaasun, o gbe ina atupa kan ti n jo bulabula si okan ninu awon ori re. Eru wa tubo
bere si bami, mo le tipetipe mo ara ogiri. Alujanu bo ni odo mi, t'oun t'enu e, eni to n gba ilekun mi o da owo duro. Oran de!

Bi o ti ku bi ẹsẹ bata meta ki o de ọdọ mi mo sun sẹyin tiberu toun tomije l'oju. Lojiji leni ton gba ilekun ja wọlé. Loba di iwin ti mo sebi moti
pa nigba ti mo se irin ajo lọsi oko ìbẹrù l'ọdun to koja. Haa!! Oran di meji. Alujanu olori mẹwa ati iwin to wa gbesan.

Oko iberu wa ni inu igbo abami ni ilu awon amunimuye, ibe ni mo ti koko s'agbako iwin to wole wa gbesan yii.
Oruko re ni n je Iberubojo Ode Aye, egbon si lo je si Ebora igberaga ode aye ti n gbe ni ona oke ironu, ni agbede meji orun ati aye. "Nibo lo fe salo? Iwo ta a fe sun to tun wa fi epo para" Iwin ke mo mi. Ohun iyalenu kan sele nibi ti awa meeteta wa. Kaka ki Alujanu pami,
ina ori re lo gbe fun mi, o ni ko le je ki enikeni se mi ni aburu. Lesekanna, Alujanu poora. Inu iwin yi baje pupo bi o ti ri oun ti Alujanu se, oun na ba binu poora.

Ara mi bere si bale, oogun to n jade ni agbari mi leekan tun ti bere si gbe. "Kini n o fi atupa alujanu
se bayii?" mo n soro si'ra mi. Nibi ti mo ti n ronu, iji kan ba tun bere si ja, gbogbo nkan to wa ni yara mi lo tuka. Bi mo ti ni kin tun sare bo sita ki n lo wo oun to n sele, ko mo lo je pe awon ara ibi ni won tun pada de, ori ibusun mi ni mo ti laju. Ah! Ko je je be? Gbogbo
oun to n sele si mi lateekan, oju ala ni? Kayeefi re o! Eru n bami, agun re ni gbogbo ara mi yii, mo ti yara dide joko, mo n mi tupetupe bi eni ti won jigbe. "Iru ala abami wo leleyi?" Mo n da so. Ile o si ti mo, boya n o ba yara lo gbe oro ala yii ba ojogbon kan ni agbole
Ogbonsayero. Agbole Ogbonsayero ko jinna si agbole odo wa, Agbole Imokayeja. Ogbonsayero ni awon Ojogbon poju si ni ode aye, Imodiran Ologbonsoriejako si ni o n se alakoso agbegbe na.

Nibi ti mo ti n ro orisirisi oran po mo'ra won ati itumo ala mi eekan, gongo miran tun so!
Ilekun ile mi ma tun bere si dun, o n dun kikankikan bi ilu agidigbo. Ariwo didun ilekun naa ko yato si ti oju ala mi eekan yen. Kayeefi gan lo tun wa je nigba ti ajeeji eda to wa leyin ilekun naa fo'hun.
Se emi nikan ni mo kuku wa nile, oun ni ko je ki awon iyawo mi ati omo se alabapade oran oru oni. Won ti lo ki awon eeyan iya mi lati bi ose kan seyin, ojumo oni gan ni won so pe awon yoo pada de. "Ajilalaoso omo Akanbi, Ajilalaoso omo Akanbi!!
Silekun ile re fun mi, odo re ni mo n bo" bee ni ohun eyin ilekun naa n pe mi, bo ti se pemi ni oju ala mi.

**************
(Continued in Episode 2.)
Missing some Tweet in this thread? You can try to force a refresh.

Enjoying this thread?

Keep Current with Ayo of Ibadan

Profile picture

Stay in touch and get notified when new unrolls are available from this author!

Read all threads

This Thread may be Removed Anytime!

Twitter may remove this content at anytime, convert it as a PDF, save and print for later use!

Try unrolling a thread yourself!

how to unroll video

1) Follow Thread Reader App on Twitter so you can easily mention us!

2) Go to a Twitter thread (series of Tweets by the same owner) and mention us with a keyword "unroll" @threadreaderapp unroll

You can practice here first or read more on our help page!

Follow Us on Twitter!

Did Thread Reader help you today?

Support us! We are indie developers!


This site is made by just two indie developers on a laptop doing marketing, support and development! Read more about the story.

Become a Premium Member ($3.00/month or $30.00/year) and get exclusive features!

Become Premium

Too expensive? Make a small donation by buying us coffee ($5) or help with server cost ($10)

Donate via Paypal Become our Patreon

Thank you for your support!