Ago mẹ́fà ló lù yìí, Àlàní ti bẹ̀rẹ̀ síí palẹ̀mọ́ fún wẹ̀jẹwẹ̀mu tí yíò sọ̀kalẹ̀ si ara òhun, àti àwọn tí ọ̀gá àgbà kan ní ilé iṣẹ́ wọn fi ìwé pè. Ní ilé ìtura Gódìn tọlìbù ni alárè ó ti j’àgbá, tí ǹkan ó gbe ǹkan hánu ni dédé ago méje tí àríyá ó bẹ̀rẹ̀ síí gbá
yùn. Kí ago mẹ́fà tó lù, orun ni Àlàní fi gbogbo ọjọ́ sùn nítorí ọjọ́ sátidè ni, iṣẹ́ á máa gb’omi mu púpọ̀ ni ààrin ọ̀sẹ̀, nítorí irú iṣẹ́ tí ó ń ṣe.
Ilé ìfowópamọ́ kan báyìí, tó wà ní ojú ọ̀nà Bódìjà ni Àlàní ti ń ṣe iṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oṣù kẹfà ọdún
2020, èyí tí a wà yìí, ni ó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, Àlàní ti ṣe dáradára fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọkùnrin. Ní inú oṣù kẹ́jọ tí a wà yìí, ni ó tún gba ìgbéga ni ẹnu iṣẹ́. Ilé rẹ̀ ti ó ń kọ́ ní Ajíbọ́dẹ náà, kò ní pẹ parí.
Òhun nìkan ni lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, síbẹ̀, ọmọ kan bíi igba ọmọ ni. Babárímisá ni Àlàní ọmọ Òpómúléró mọjaàlekàn, láti kékeré rẹ̀ ni Bàbá ti fi ilẹ̀ ṣe aṣọ bora. Ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ọrùn tí kò jẹ́ kí orí jábọ́, ìyá Àlàní ṣe gudugudu méje, yàyà mẹfà tó fi de ibi
gíga yìí. Bi Àlàní ti bọ́ síta ní ilé ìwẹ̀, pẹ̀lú tówẹ́lí tó lọ́ mọ̀ ìdí, tí omi sì n ro tó ní ara rẹ̀, ẹni tó bá rí ọkùnrin tí à ń sọ yìí ní àsìkò náà, àwòtúnwò ni yíò wòó lógun nítorí ẹwà tí Èdùmàrè fi jíìnkí rẹ̀.
Ojú rẹ̀ ló tàn rekete bíi iná alẹ́ yìí, irun orí
rẹ̀ kò kún jù, irùngbọ̀n rẹ̀ tó kún, tó sì bòó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ yìí, ni àwọn tó ń jí fún ṣe gba tirẹ̀. Àwọ̀ rẹ̀ Pupa, ó sì wùn ni jọjọ. Ìdúró rẹ̀ wu ènìyàn tó bẹ̀ gẹ̀ẹ́, tí àwọn kan tún ma ń bèrè lọ́wọ́ rẹ̀, bóyá ‘módẹ̀lì’ ni. Ká fi àsọdùn sílẹ̀,
Àlàní rí owó túnra ṣe. Bó ti para tán, ó kósí 'sẹ́ẹ̀tí' aláràǹbarà àti ṣòkòtò pénpé kan. O fi fílá kan dé ìmúra rẹ̀ lórí. Ṣé àwọn tó fi ìwé pè wọ́n sọ nínú ọ̀rọ̀ wọn pé “Dress code: Casual & keep it simple”. Nígbà tó fín lọ́fíndà sí aṣọ tán, ó bọ́ síta, ó sì
lọ fún àwọn ara ilé rẹ̀, ni 'fúlàtì' kejì ní kọ́kọ́rọ́. Òhun nìkan ló ń gbé ilé. Ẹ̀kọ̀kan ni àfẹ́sọ́nà rẹ̀ àti Ìyá rẹ̀ ma ń wálé.Àlàní kósí inú mẹ̀sí ọlọ́yẹ́, ó wo ago ‘Rólẹ̀sì’ ọwọ́ rẹ̀, ago mẹ́fà àbọ̀ ló lú, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ń fi àtẹ̀jísẹ́ ránṣẹ́
si lórí 'wọ́sọọ̀bù', wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ó ti kúrò nílé. Ṣùgbọ́n, kò dá ẹnìkan lóhùn. Ó ṣ'áná sí ọkọ̀, ó sì ń bá tirẹ̀ lọ sí òde. Rẹ́díò ọkọ̀ náà ń gbé orin' híbúhọbù' orísirísi sí afẹ́fẹ́ bí Àlàní ti ń g’ẹṣin lọ. Bi ‘Dafidó’ bá kọ tirẹ̀ tàán, ‘Bọ́nàBọì’
á gbàá ní ẹnu rẹ̀, ‘Wísíkidì’ náà àti àwọn olórin mìíràn ni gbẹ̀du wọn ń wọ akínyẹmí ara Àlàní.
Nígbà tó kúrò ní ilé rẹ̀ ní ìdí-àpẹ́, ọ̀nà ọ́físási mẹẹ̀sì ni ó darí ọkọ̀ rẹ̀ gbà, yíò gba ọ̀nà yẹn já sí 'kọ́sítọ̀mù'. Láti ibẹ̀, yíò nàá gba títì Awólọ́wọ̀,
tí yíò fi bọ́ sí Sángo. Jẹ́ríkó ni òpin ìrìn àjò kékeré yìí, nítorí ibẹ̀ ni ilé ìtura tó ń lọ wà.
Bí Àlàní ti dé iwájú Ìkọ́làbá, ní ìtòsì ‘Kọ́sítọ̀mù’ ni ọkọ̀ rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sií yọ ọwọ́kọ́wọ́, tí ó ń ṣe èsúkè léraléra. Kí Àlàní tó gbìyànjú láti yà níbi ìyànà
tó wà ní iwájú ilé ìwé Ìkọ́làbá lọ sí 'Kọ́sítọ̀mù', ọkọ̀ rẹ̀ gbé ẹ̀mí mì o. “irú kíni èyí ní àsìkò tí mò ń kánjú báyìí? Ah!” Ó ń dá sọ̀rọ̀ bí ó ti ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀. Àwọn èèyàn bíi mẹ́ta tí wọ́n ń ta èso oríṣiríṣi kan wà ní ibẹ̀ yẹn.
Àlàní ń gbìyànjú láti jí mọ́tò náà padà, ṣùgbọ́n, pàbó ni ó já sí. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tó ń ta ọjà yẹn, ó kọjú sí obìnrin tó kọ pélé kan báyìí.
Ó bèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ obìnrin náà, ó ní “ẹ jọ̀wọ́, ṣé mo lè rí ‘mẹkánìkì’ ní àárín yìí?” Obìnrin náà kọ́kọ́ wo apá
àláfíà rẹ̀ lọ sùn, ní ibi tí igi rẹ̀gẹ̀jì kán àti àwọn 'ṣọ́ọ̀bù' kan wà, ni ó ń wò. O pe ẹnìkan, “Bọ̀dá Sàráfà! Sàrá! Sàrá o! Bọ̀dá Sàráfà!” Ìyẹn náà dáhùn láti abẹ́ igi tó wà, ó ní “Kílódé tí ẹ̀ ń pariwo mi? Ṣé mo dákú ni?”
Obìnrin náà tún dáhùn, ó ní, “Àwọn ‘kọ́sítọ́mà’ ni wọ́n ń bèrè bọ̀dá Àlàbá o”
“Àlàbá ní ago méje? Ẹni tí ìyàwó rẹ̀ b'ímọ sílé. Bí ó bá ń rákòrò, yíò ti dé Mọ́níyà” Sàráfà fèsì padà.
Bí Àlàní ti gbọ́ báyìí, ó wo ojú obìnrin yẹn, onítọ̀hún náà wòó padá, Àlàní dúpẹ́
lọ́wọ́ obìnrin náà, o si padà sí ìdí ọkọ̀ rẹ̀ láti wá ọ̀nà míràn gbée gbà.
Bí iná ò bá tán l’áṣọ, ẹ̀jẹ̀ kìí tán l'éèkánná. Àlàní dúró ní iwájú ìlẹ̀kún àyè dẹ́rẹ́bà, ó fẹ̀yìn ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ rẹ̀, ó ń tẹ fóònù, mọkálìkì ni ó fẹ́ pé. Ó gbé fóònù sí etí ní ìrètí
pé, ẹni tí òhun ń pè, yíó gbe. Àwọn mọ́to ń kọjá ní méjì mẹ́ta lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí Àlàní lọ bá ní ẹ̀kan, ti ń palẹ̀mọ̀ọ́. Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, gbogbo ilé tí ó wà ní àyíká ni wọ́n ṣe 'géèti' sìí, tí ẹnìkan kò jáde tàbí wọlé ní àkókò yìí. Ago méje kọjá ìṣẹ́jú
mẹ́ẹ̀wá ló lù yìí, ṣùgbọ́n, ojú ọjọ́ kò tíì pajúdé, gbogbo ohun tó ń lọ ni èèyàn léè rìí.
“Ẹ̀ló! Ẹ̀ló! Ṣé ẹ̀ ń gbọ́ mi?” Àlàní ń bá mọkálìkì rẹ̀ sọ̀rọ̀.
Mọkálìkì fèsì, “Ẹ̀gbọ́n tó jaiyé jù! Mò ń gbọ́ yín”
Àlàní tún dáhùn, ó ní, “Mọ́tò mi ló takú ní ibi
ìyànà Ìkọ́làbá yẹn, mo dẹ̀ ni 'patí' tí mò ń lọ”
“Kílóṣe é gangan?”
“Ẹ wòó, mi ò mọ̀ ní kókó. Ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ máa bọ̀, màá san’wó yín”
“Mo wà ní inú àdúgbò kan ní Olódó, màá dé ọ̀dọ̀ yín l'áìpẹ̀ẹ́”
Bí Mọkálìkì ti wí báyìí tán, ọkàn Àlàní tún balẹ̀ díẹ̀,
nítorí, ó mọ̀ pèé, lọ́gán tí Ọkùnrin mọkálìkì yẹn bá dé, ọkọ̀ náà yíò gba ìwòsàn. Kó pẹ̀ ti ó pe mọkálìkì tàán, tí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tún ki orin b'ọnu nínú àpò ṣòkòtò.
Nígbà tí Àlàní mú ẹrù síta, ẹni tí ó ń pèé di Kúnlé, ìkan nínú àwọn ọ̀rẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n
dìjọ ń ṣisẹ́ ní Bódíjá. Bí ó ti gbé ìpè yẹn, irú ariwo tó ń jáde ní abẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kúnlé ní ọ̀hún fi hàn dájú pé àríyá ti ń sọ lálá.
“Ọ̀rẹ́ wa! Níbo lo wà báyìí? Àwọn 'bọ́ìsì' ti tẹ́ pẹpẹ fàájì sí ibí o! Kílódé? Níbo lo wà?” Kúnlé ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ bí
Àlàní ti gbé ìpè.
Àlàní náà tún dáhùn, ó ní, “Ọmọ! Oò ní 'bìlíìfù' ọṣẹ tó lọ yí mi ṣá? Mọ́tò mi ló takú o!”
“Ahh! Níbo? Ṣe ‘mẹkánìkì’ ti wà níbẹ̀ yẹn?” Kúnlé fèsì.
“O mọ ibi ìyànà Ìkọ́làbá lọ sí ‘Kọ́sítọ̀mù’ yẹn? Ibẹ̀ ni wèrè ara rẹ̀ paná sí! Mẹkánìkì ti ń
bọ̀ ṣàá” Àlàní ń sàlàyé fún Kúnlé báyìí.
Kúnlé tún dáhùn, ó ní, “Mi ǹ bá ní ko fi mọ́tò yẹn síbẹ̀ d’ọ̀la ṣùgbọ́n, ǹkan léè ṣeé níbẹ̀ mọ́júmọ́”
“Ahh! Ní àdúgbò tó ti dá yìí! Gbogbo àwọn ọlọ́jà tí mo bá, ni wọ́n ti lọ” Àlàní tún fún lésì.
Kúnlé ní, “Èmi àti Akin
ma 'díráìfù' wá bá ẹ níbẹ̀ kó má ṣe ìwọ àti mẹkániki nìkan”
“Wàá ṣere ọmọ ìyá mi! Ẹ bámi gbé àwọn jíjẹ mímu ti òdé wá o” Bi Àlàní ti parí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀, tó ní kí òhun fi ìkàlẹ̀ si nínú ọkọ̀, ni ó gbọ́ tí ọkọ̀ kan ń panà ní ẹ̀yìn ọkọ̀ rẹ̀.
Bi Àlàní ti gbé ojú wo ibẹ̀, mọ́tò àwọn agbófinró ni ó rí ti àwọn ọkùnrin méjì sì sọ̀kalẹ̀ láti inú rẹ̀. Ẹni wẹjú ni ẹ̀rù ń bà, Àlàní ò mira bí ó ti rí àwọn ọlọ́pàá nítorí kò ṣe ǹkan ẹ̀rù. Àwọn méjèèjì yẹn mú orí lé ọ̀dọ̀ Àlàní, ìkan nínú wọn kúrú, o
dúdú bíi ìsàlẹ̀ kòkò ẹ̀wà, ó sì ṣe ikùn gbẹ̀ndù bíi akèrègbè ẹmu, ó mú kóndó kan báyìí lọ́wọ́. Èkejì náà ga, ó dúdú, ó sì tún síngbọnlẹ̀, ìbọn ni ó fi ṣe ọ̀sọ́ sí ọwọ́ kan. Ọlọ́pàá tí kò ní Ìbọn, tí kò ní kùmọ̀, kòì tíì ṣe orò iṣẹ́ pé.
Bí ara wọn ti ń bù tì fún pàrágà tó, ìsọ̀rọ̀ sí wọn fi hàn gedegbe wípé, ọtí kò tíì gbé ọpọlọ wọn l'ugbò. Bí wọ́n ti dé ọ̀dọ̀ Àlàní, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé e ní ẹnu jó. Ní dédé àsìkò yìí, àwọn ọlọ́jà ti bá ti wọn lọ, àdúgbò náà ti dá bíi ìkómọ dìdìnrìn.
(To be continued).
À Rìn Fẹsẹ̀ Sí Ò Kan Máìlì - 📝 Ayọ̀ Adams.
• • •
Missing some Tweet in this thread? You can try to
force a refresh
Colors of an African Market shows the different activities of buyers and sellers at Bodija, a popular market in Ibadan, Nigeria. It is a reflection on the daily hustle and bustle of people from varying backgrounds who are united by a common location- the market.
It is also a mirror of life which has been described to be a market where people come and go when the time calls.
À Rìn Fẹsẹ̀ Sí Ò Kan Máìlì 2- 📝 Ayọ̀ Adams.
__
Kedere ni Àlàní ń rí orúkọ tí ó wà ní ara aṣọ àwọn ará ibí. Èyí dánkú yẹn ni wọ́n kọ “W.O Aliu” sí aṣọ rẹ̀, tí “F. Bánjọ” sì wà ní ti èkejì.Lọ́gán tí wọn ti dé ọ̀dọ̀ Àlàní, ni Aliu ti ṣí ìlẹ̀kùn iwájú apá
àlàáfíà, tó sì ń tú ọkọ̀ ọlọ́kọ̀ bíi pé, ó tọ́jú ǹkan sí ibẹ́. Aliu wà ní ẹnu èyí, ni Bánjọ ń ju ìbéèrè sí Àlàní. Ó k'ẹhùn sọ̀rọ̀, ó ní, “Misita man! Kíni ìwọ ń ṣe níbí ní ìwòyí?”
Aliu gbé orí sókè láti ibi ìlẹ̀kùn tí ó k’orí bọ̀ tẹ́lẹ̀, ohun náà tún ní, “Àwọn
ìyókù rẹ dà? Àbí, ìwọ ni wọ́n ní kí o máa ṣọ́ ilẹ̀?” Bí Àlàní ti fẹ́ fèsì, Aliu tún gba ọ̀rọ̀ mọ́ọ lẹ́nu, ó ní, “Àbí, o wà lára àwọn alọk’ólóun kígbe tí ó ń da omi àdúgbò yìí rú? Wo ojú rẹ̀ kóíkóí bíi ojú ẹmọ́."
Work is the antidote for Poverty
Work diligently, my friend
Being industrious brings success
If we have no one to lean on
It is as if one is lazy
If we have no one to support us
We invest diligently in our work
Your mother might be rich
And your father may have a stable full of horses
If you rely on them
You are on a journey to disgrace, I tell you.
Whatever one does not labour for
Does not last
That which you earned by virtue of hardwork
Lasts in the hand
Your arm is family
The elbow is your sibling
If the world loves you today
If you have money
The world will love you tomorrow
Or when you are in an honorable position
With cheerful smiles, the world will celebrate you
When your fortune changes
The world will mock you
Isẹ́ lògùn ìṣẹ́
Múra sí Isẹ́ ọ̀rẹ́ mi
Iṣẹ́ ni a fí n d’ẹni gíga
Bí a kò bá rẹ́ni fẹ̀yìntì
Bí ọ̀lẹ làá rí
Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé
A tẹra mọ́ṣẹ́ ẹni
Ìyá rẹ le lówó lọ́wọ́
Bàbá rẹ sì le lẹ́ṣin léèkàn
Bí o bá gbójú lé wọn
O tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ
Ohun tí a kò bá jìyà fún
Sé kìí leè tọ́jọ́
Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ́ fún
Ní ń pẹ́ lọ́wọ́ ẹni
Apá lará
Ìgúnpá ni ìyè kan
Bí ayé bá ń fẹ́ ọ lónìí
Tí o bá lówó lọ́wọ́
Wọ́n á ma fẹ́ ọ lọ́la
Tàbí kí o wà ní ipò
àtàtà
Ayé á máa yẹ́ ọ sí tẹ̀ríntẹ̀rín
Jẹ́ kí o dẹni tí n rágó
Kóo rí bí ayé ti ń yínmú sí ọ
Ẹ̀kọ́ sì tún sọni dọ̀gá
Múra kí o kọ́ọ dáradára
Bí o sì r’ọ́pọ̀ ènìyàn
Tí wọ́n n f’ẹ̀kọ́ s’ẹ̀rín rín
Dákun má fara wé wọn
Díẹ̀kọ́lá fa Akin mọ́ra pẹ̀lú agbára, àwọn méjèjì ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ ètè ara wọn jẹ bi pọ̀mọ́ aláta súẹ́súẹ́. Nígbà tí Díẹ̀kọ́lá wọ inú 'ọ́fìsì' yẹn wá lẹ́ẹ̀kan, ó ti t'ilẹ̀kùn pa. Bí ẹnikẹni yóò bá wọlè, wọn á kan ilẹ̀kùn. Bí ètè jíjẹ ti ń wọra,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sún láti ibi kan sii èkejì nínú 'ọ́fìsì' Akin. Síbẹ̀, iṣẹ́ ẹ́nú àti ahọ́n ń lọ ní rẹ́surẹ́su. Bí wọ́n ti sún sí orí àga kan báyìí, ni àwọn méjèjì bá bẹ̀rẹ̀ sí gba aṣọ kúrò ní ara wọn. Bí ẹni kíni ti ń sáré bọ́ ti èkejì, ni èkejì náà ń ṣe
bàlàbàlà gba ti ara ìkíní. Wọ́n ń wọ ìdìmú ara bí ẹ́ni tí wèrèpè kán lù. 'Súùtí' tí Akin wọ̀ rèé ní orí 'rọ́ọ̀gì', 'sẹ́ẹ̀tì' náà ń serè ní etí àga. Gbogbo ohun tí Díẹ̀kọ́lá náà tò mọ́ ara ti wá ibi gba.
Eré àníyàn fẹ́ ma wọra nínú 'ọ́fìsì' Akin. Ó ti ku ṣòkòtò
If D.O Fagunwa was alive and he writes about the Pandemic - (Ep. 1)
_____
Ni oru ojo kan bayii, owo ti pa, ese pa, o to asiko t'omokekere ile o gbodo sunkun omu. Lojiji, mo beresi gbo ti ilekun ile mi n dun, eru bami. Mo sokan giri, mo gba enu ona lo. "Ajilalaoso omo Akanbi,
silekun ile re fun mi, odo re ni mo n bo" ohun na ke simi lati ibi ilekun. Eru tun bami, mo ro pe tani iru eda to le mo oruko emi ati iya mi loganjo?
Eyi tubọ bami l'eru gidigidi nítorípé bi wọn ti pe Kàkó ore mi pa nù. Bi motin wariri lọwọ bẹẹni mo ri ti iya mi yo
simi o funmi ni iye odidẹrẹ pupa kan, o ni kin fi si inu epo pupa kin si fi le tiro si oju mi. Mo ṣe be, ketete ni mo si ri alujanu olori mẹwa kan ni yara mi.
Alujanu yii dudu hoho bi isale isaasun, o gbe ina atupa kan ti n jo bulabula si okan ninu awon ori re. Eru wa tubo